Jump to content

Ositiro-Esiatiiki

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ositiro-Esiatiiki

Austro-Asiatic

Àwọn èdè tí ó wà nínú ẹbí èdè yìí tó àádọ́sàn-án. Àwọn tí ó ń sọ wọ́n tó mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin. Gúsù ìlà-oòrùn Asia ní pàtàkì ní China àti Indonesia ni wọ́n ti ń sọ wọ́n jù. Àwọn kan sì tún ń sọ wọ́n ní apá ìwọ̀-oòrùn àríwá India àti ní Erékùsù Nicobar (Nicobar Island). Àwọn ẹ̀yà mẹ́ta ẹbí èdè yìí tí ó ṣe pàtàkì ni Mon-Khmer (tí ó jẹ́ pé nínú rẹ̀ ni àwọn èdè pọ̀ sí jù), Munda àti nicobarese. Àwọn méjèèjì tó gbẹ̀yìn yìí ni wọ́n ń sọ ní ìwọ̀-oòrùn àdúgbò Mon-khmer. Láti fi ìmọ̀ ẹ̀dá èdè pín àwọn èdè yìí sòro díẹ̀ nítorí pé díẹ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó ní àkọsílẹ̀ àti pé ìbáṣepọ̀ tí ó wà ní àárín àwọn ẹbí èdè yìí àti àwọn ẹbí èdè mìíràn kò yé èèyàn tó.