Philippe de Champaigne
Philippe de Champaigne | |
---|---|
Philippe de Champaigne, self-portrait. Museum of Grenoble | |
Pápá | Àwòrán yíyà |
Movement | Baroque |
Philippe de Champaigne (ìpè Faransé: [ʃɑ̃paɲ]; Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n Oṣù karún Ọdún 1602 – Ọjọ́ kejìlá Oṣù kẹjọ Ọdún 1674) jẹ́ ayàwòrán ará Faransé tí a bí sí Brabançon , tí ó jẹ́ olùgbéga ilé ẹ̀kọ́ Faransé. Ó jẹ́ ara àwọn olùdásílẹ̀ Académie de peinture et de sculpture.
Ìgbésíayé àti iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bíi sí ẹbí òtòṣì kan ní Brussels (Duchy of Brabant, Gúúsù Netherlands), nígbà ayé Archduke Albert àti Isabella, Champaigne jẹ́ akẹ́kọ́ lọ́wọ́ olùyàwòrán tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jacques Fouquières. Ní ọdún 1621 ó kọjá sí Paris, ní ibi tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Nicolas Poussin níbi ìṣẹ̀ṣọ́ fún Palais du Luxembourg lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Nicolas Duchesne, tí ó fẹ́ ọmọ rẹ̀ married. Gẹ́gẹ́ biHoubraken ti sọọ́ di mímọ̀, inú bí Duchesne sí Champaigne nítorí wípé ó gbajúmọ̀ jùú lọ ní court, èyí ni ó jẹ́ kí Champaigne padà sí Brussels láti lọ maa gbé pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ìgbà tí ó gbọ ìròyìn nípa ikú Duchesne ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ padà lọ fẹ́ ọmọ rẹ̀.[1] Lẹ́yìn ikú olùdáàbòbò Duchesne, Champaigne ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyá olorì, Marie de Medicis, tí o ti wa lára àwọn tí ó ṣe ààfin Luxembourg lẹ́ṣọ́.Ó yà àwọn àwòrán oríṣíríṣí fún Notre Dame Cathedral ní Paris, ní bíi ọdún 1638 sẹ́yìn. Ó tún ya àwọn àwòrán oní bèbí sí orí aṣo. Wọ́n yàn-án ní ayàwòrán àkọ́kọ́ fún olorì tí ó sì gba ẹgbẹ̀rún àti igba pọ́nhùn fún iṣẹ́ rẹ̀. O tún ṣe ẹ̀ṣọ́ fún ilé ìjọsìn Carmelite ti Faubourg Saint-Jacques, tí ó jẹ́ ìkan lara àwọn ilé ìjọsìn tí Iyá Olorì yàn lààyò.
Wọ́n ba ibẹ̀ jẹ́ nígbà àyípadà Faransé ṣùgbọ́n àwọn àwòrán wà tí wọ́n tọ́jú sí àwọn ilé ọnà tí ó wà lára àwọn ẹ̀ṣọ́ àkọ́kọ́ (Èyí tí wọ́n ṣe ní pẹpẹ wà ní Dijon, àjínde Láśarù wà ní Grenoble tí ìgbàbọ́ ìbálé sì wà ní is Louvre.
Ó tún ṣiṣẹ́ fún Cardinal Richelieu, tí ó ṣe ẹ̀ṣọ́ Palais Cardinal, tí ó jẹ́ òfúrufú Sorbonne àti àwọn ilé míràn. Champaigne ni oníṣẹ́ ọnà tí wọ́n gbà láàyè loáti ya àwòrán Richelieu tí wọ́n fi sàmì, tí ó ṣe ní ìgbà mọ́kànlá. Ó wà lára àwọn olùdásílẹ̀ Académie de peinture et de sculpture ní ọdún 1648. Nígbà ayé rẹ̀ (láti 1640 síwájú si), ó ṣalábápàdé Jansenism. Lẹ́yìn ìyanu tí ó gbé ọmọ rẹ̀ tí kò lè rìn dìde ní Port-Royal, ó ya àwòrán ẹ̀yẹ yìí Ex-Voto de 1662, tí ó wà ní Louvre, tí wọ́n fi ṣàpèjúwe ọmọ ayàwòrán yìí pẹ̀lú ìyá olọ́lájùlọ Agnès Arnauld.
Ìṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Champaigne ya àwọn àwòrán tó pọ̀, tí ó ní ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ẹ̀sìn. Rubens tọ́ọ sọ́nọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sí dára. Philippe de Champaigne jẹ́ ayàwòrán tí iṣẹ́ rẹ̀ yàtọ̀, a dúpẹ́ fún àwọn àwọ̀ àrànbarà tí ó maa ń tayọ ní iṣẹ́ rẹ̀.[2]
Ilé àwòrán rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]-
The Annunciation, c. 1645, Wallace Collection
-
Repentant Magdalen ní ọdún 1648
-
Le sacrifice d'Isaac
-
Mósè pẹ̀lú àwọn òfin mẹ́wá
-
Ecce Homo
-
Saint Augustin, 1645–50
-
Saint Paul
-
Àwòrán Arnauld d'Andilly, 1650, Louvre
-
Louis XIII ti France ní Ìwúyè, c. 1622–39.
-
Àwòrán ti Cardinal de Richelieu, c. 1642, National Gallery, London
-
Portrait of Jean-Baptiste Colbert, 1666
-
Àwòrán Omer Talon, 1649
-
Charles II ti England, 1653
-
Àwòrán François Mansard àti Claude Perrault, 17th century.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Philips de Champanje biography in De groote schouburgh der Nederlantsche konstschilders en schilderessen (1718) by Arnold Houbraken, courtesy of the Digital library for Dutch literature
- ↑ "Getty Artists Philippe de Champaigne". www.getty.edu. Retrieved October 2014. More than one of
|accessdate=
and|access-date=
specified (help); Check date values in:|access-date=
(help)