Badagry
Àgbádárìgì | |
---|---|
Ìlú | |
Ọjà Àgbádárìgì ní ọdún 1910 | |
Ifihàn Àgbádárìgì ní ìlú Èkó | |
Coordinates: 6°25′N 2°53′E / 6.417°N 2.883°E | |
Orílẹ̀ Èdè | Nigeria |
Ìpínlẹ̀ | Ìpínlẹ̀ Èkó |
LGA | Àgbádárìgì |
Area | |
• Total | 441 km2 (170 sq mi) |
Population (2006) | |
• Total | 241,093 |
Time zone | UTC+1 (WAT) |
Website | www.badagrygov.org |
Àgbádárìgì tí a kọ́kọ́ mọ̀ sí Gbagle láti ìbèrè jẹ́ ìlú ẹ̀bádò àti ìjoba ìbílè ní ipínlè Èkó, lórílẹ̀-èdè Nàìjíría. Àgbádárìgì gúnwà láàárín Ìlú Èkó àti orílẹ̣̀-èdè Olómìnira Benin. Èyí jásí wípé, Ó tún jẹ́ ìlú alálà Nàìjíría àti orílẹ̣̀-èdè Olómìnira Benin ni Sèmè.[1]. Gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ètò ìkànìyàn ọdún 2006, àpapọ̀ iye enìyàn tó wà ní Àgbádárìgì jẹ́ 241,093.[2]
Àgbègbè Ìtèdósí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àgbádárìgì jẹ́ ìlú tí a tẹ̀dó si ẹ̀bádò ìwọ̀-òorùn Nàìjíría. Ó jẹ́ ìlú tó pàlà pẹ̀lú Gulf of Guinea làgbègbè gúsú. Ó wọn ìwọ̀n máìlì mẹ́tàdínlógójì (43) ní apá gúsú ìwọ̀-òorùn ti ìlú Èkó, bákan náà ó wọn ìwọ̀n máìlì mẹ́jìdínlọ́gbọ̀n (32) ní apá ìwọ̀-òorùn ní ìlú Sẹ̀mẹ̀ tí ó pàlà pẹlú orílẹ̣̀-èdè Olómìnira Benin. Gẹ́gẹ́bí erékùsù Èkó, Àgbádárìgì jẹ́ ìlú tí a tẹ̀dó sí etí omi, nítorí ìdí èyí, àyè wà láti rìnrìn-àjò gbojú omi láti Èkó sí Ìlú Porto Novo. Àlàfo tó wà láàárín òkun àti ọ̀sà dá lórí ẹ̀bádò, ní Àgbádárìgì, ó tó máìlì kan sí ara wọn. Jíjìnà àwọn òdò wònyí máa ń dá lórí irú àsìkò tí a bá wà, ó máa ń jìnnà bíi ìwọ̀n mítà mẹ́ta bí òdò kuń dẹ́nu, Ṣùgbọ́n lásìkò ọ̀gbẹḷẹ̀, ó máa ń jìnnà bíi ìwọ̀n mítà ẹyọ kan. Onírúurú ọ̀pọ̀ ẹja ló wà nínú àwọn òdò wọ̀nyí, lára àwọn ẹja tó wà nínú òdò Àgbádárìgì ni; ọ̀bọ̀kún, èpìà, àrọ̀, kókà, bongá at pompano. Omi inú àwọn odò Àgbádárìgì máa níyọ̀ nínú ní àwọn àsìkò kan, bẹ́ẹ̀ kìí níyọ̀ láwọn àsìkò mìíràn, ìṣàn omi láti apá iwọ́-oòrùn ìlú náà àti odò Yewa ló máa ń ṣàn sinu odò Àgbádárìgì.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Interesting Facts That Put Badagry On The Map". Guardian Life. Archived from the original on 2018-06-28. Retrieved 2018-07-21.
- ↑ The area is led by a traditional chief, Akran De Wheno Aholu Menu - Toyi 1, who is also the permanent vice-chairman of obas and chiefs in Lagos State. Federal Republic of Nigeria Official Gazette Archived 2007-07-04 at the Wayback Machine., published 15 May 2007, accessed 8 July 2007