Naples
Ìrísí
Ìlú kan tí ó se pàtàkì nínú ìtàn ni Naples. Gúsù ilè Italy ni Naples wà. Àwon ènìyàn tó n gbé ibè tó 1,278.000. Òun ni ìlú tí ó tóbi se èkéta ní ilè Italy. Ó tèlé Rome àti Milan.
Àwón ènìyàn, máa n rin ìrìnàjò afé lo sí ìlú yìí. Wón máa n kan okò ojú omi nlá níbè. Wón ní àwon èso wón sì ní àwon ilé-isé tí ó n so epo dòtun.
Àwon Greek ni ó dá Naples sílè sùgbón ó bó sí abé àse Róòmù ní séntúrì kérin sáájú ìbí Kírísítì. Ó dá dúró funra rè ní séntúrì kéjo léyìn ikú olúwa wa. Léyìn èyí ni ó wá di olú-ìlú fún ìjoba Sialy àti Naples. Naples dara pò mó Italy ní 1861.